2 Kings 19:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Aisaya ọmọ Amosi ranṣẹ sí Hesekaya ọba pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Mo ti gbọ́ adura rẹ nípa Senakeribu, ọba Asiria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, adura ti iwọ ti gbà si mi si Sennakeribu ọba Assiria emi ti gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán oníṣẹ́ sí Heṣekíàyà pé: “Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Ṣenakérúbù ọba Ásíríà.