2 Kings 19:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà, o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè, títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni; mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ, Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ, mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipa awọn onṣẹ rẹ, iwọ ti sọ̀rọ buburu si Oluwa, ti nwọn si wipe, Ọpọlọpọ kẹkẹ́ mi li emi fi de ori awọn òke-nla, si ori Lebanoni, emi o si ké igi kedari giga rẹ̀ lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀; emi o si lọ si ori òke ibùwọ rẹ̀, sinu igbó Karmeli rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ìwọ ti ṣe ìkójọpọ̀ èébú sí OLÚWA. Ìwọ sì ti sọ pé, “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi Èmi sì ti fi dé orí àwọn òkè ńlá, ibi gíga jùlọ ní Lébánónì Mo sì ti gé igi gíga jùlọ kédárì lulẹ̀, àti àyò igi fírì rẹ̀. Mo ti dé ibi orí òkè ìbùwọ́ ẹ̀gbẹ́ kan ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ.