2 Kings 19:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣé o kò mọ̀ pé ó pẹ́ tí mo ti pinnu àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ wọnyi ni? Èmi ni mo fún ọ ní agbára tí o fi sọ àwọn ìlú olódi di òkítì àlàpà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò ti gbọ́, lailai ri emi ti ṣe e, nigba atijọ emi si ti mura tẹlẹ nisisiyi emi ti mu u ṣẹ, ki iwọ ki o le mã sọ ilu olodi wọnni di ahoro, ani di òkiti àlapa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́? Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án. Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀; nísinsìn yìí mo ti mú wá sí ìkọjá pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí òkítì àlàpà òkúta.