2 Kings 19:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà ni àwọn tí wọn ń gbé inú àwọn ìlú olódi náà ṣe di aláìlágbára, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Wọ́n dàbí ìgbà tí atẹ́gùn gbígbóná ìlà oòrùn bá fẹ́ lu koríko tabi ewéko tí ó hù ní orí òrùlé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni awọn olugbe wọn fi ṣe alainipa, a daiyàfo wọn nwọn si dãmu; nwọn dàbi koriko igbẹ́, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko li ori ile, ati bi ọkà ti o rẹ̀ danù ki o to dàgba soke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn wọn ń gbẹ nípa, wọ́n ti dàá láàmú wọ́n sì ti sọọ́ di ìtìjú. Wọ́n dà bí koríko ìgbẹ́ lórí pápá, gẹ́gẹ́ bí ọkà tí ó rẹ̀ dànù kí ó tó dàgbà sókè, gẹ́gẹ́ bí fífún ọkà tí ó hù jáde.