2 Kings 19:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun ni, ati li ọdun keji eyiti o hù ninu ọkanna; ati li ọdun kẹta ẹ fun irúgbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba ajara, ki ẹ si jẹ eso rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí yóò jẹ́ àmìn fún ọ, ìwọ Heṣekíàyà: “Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú iyẹn. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè, gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èṣo rẹ̀.