2 Kings 19:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n sì jíṣẹ́ Hesekaya ọba fún Aisaya pé, “Ọba sọ pé òní jẹ́ ọjọ́ ìrora, wọ́n ń fi ìyà jẹ wá, a sì wà ninu ìtìjú. A dàbí aboyún tí ó fẹ́ bímọ ṣugbọn tí kò ní agbára tó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Ọjọ oni ọjọ wàhala ni, ati ti ibawi, ati ẹgàn: nitoriti awọn ọmọ de oju-ibí, kò si si agbara lati bi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sọ fún ún pé, “Èyí ni ohun tí Héṣékáyà sọ: ọjọ́ òní yí jẹ́ ọjọ́ ìpọ́njú àti ìbáwí àti ẹ̀gàn, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ọmọdé wá sí ojú ìbímọ tí kò sì sí agbára láti fi bí wọn.