2 Kings 19:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ohun tí OLUWA sọ nípa ọba Asiria ni pé, kò ní wọ inú ìlú yìí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà kankan sí i. Kò sí ọmọ ogun kan tí ó ní apata tí yóo wá sí ẹ̀bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè gbìyànjú láti gbógun tì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi niti ọba Assiria, On kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio mu asà wá iwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio mọ odi tì i yika.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA ṣọ nípa ti ọba Áṣíríà: “Kò ní wọ ìlú yìí tàbí ta ọfà síbí. Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.