2 Kings 19:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni angẹli OLUWA lọ sí ibùdó ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an lé ẹẹdẹgbaata (185,000) àwọn ọmọ ogun, wọn kú kí ilẹ̀ ọjọ́ keji tó mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li oru na ni angeli Oluwa jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan le ẹgbẹ̃dọgbọn enia ni ibùbo awọn ara Assiria: nigbati nwọn si dide ni kutukutu owurọ, kiyesi i, okú ni gbogbo wọn jasi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní alẹ́ ọjọ́ náà, ańgẹ́lì OLÚWA jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Aṣíríà. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà!