2 Kings 19:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan níbi tí ó ti ń bọ oriṣa ninu ilé Nisiroku, oriṣa rẹ̀, ni Adirameleki ati Ṣareseri, àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi idà pa á, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ bá jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi o ti mbọ̀riṣa ni ile Nisroku oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣareseri awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a: nwọn si sa lọ si ilẹ Armenia. Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nísírókù, ọmọkùnrin rẹ̀ Adiramélékì àti Ṣárésérì gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Árárátì Ésáráhádónì ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.