2 Kings 19:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba Asiria ti rán Rabuṣake, olórí ogun rẹ̀ kan, láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọrun alààyè. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn yìí, kí ó sì jẹ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ níyà. Nítorí náà, gbadura fún àwọn eniyan wa tí wọ́n kù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Rabṣake ẹniti ọba Assiria oluwa rẹ̀ ti rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè, yio si ba a wi nitori ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́: njẹ nitorina, gbé adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó lè jẹ́ wí pé OLÚWA Ọlọ́run yóò gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ olùdarí pápá, ẹni tí ọ̀gá rẹ̀, ọba Ásíríà, ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè sẹ̀sín, yóò sì báa wí fún ọ̀rọ̀ ti OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún ìyókù àwọn tí ó wà láàyè.”