2 Kings 19:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó ranṣẹ pada ó ní, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé OLUWA ní kí ó má jẹ́ kí iṣẹ́ tí ọba Asiria rán sí i pé OLUWA kò lè gbà á dẹ́rùbà á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ sọ fun oluwa nyin, Bayi li Oluwa wi pe, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọnni, ti o ti gbọ́, ti awọn iranṣẹ ọba Assiria fi sọ ọ̀rọ odi si mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àìṣáyà wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Áṣíríà ti sọ̀rọ̀ òdì sí mi.