2 Kings 2:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Elija dáhùn pé, “Ohun tí o bèèrè yìí ṣòro, ṣugbọn bí o bá rí mi nígbà tí wọ́n bá ń gbé mi lọ, o óo rí ohun tí o bèèrè gbà. Ṣugbọn bí o kò bá rí mi, o kò ní rí i gbà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Iwọ bère ohun ti o ṣoro: ṣugbọn, bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃ kọ, kì yio ri bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Èlíjà wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”