2 Kings 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Eliṣa ti rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kígbe pe Elija, ó ní, “Baba mi, baba mi, kẹ̀kẹ́-ogun Israẹli ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.” Kò rí Elija mọ́, ó bá fa aṣọ rẹ̀ ya sí meji láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eliṣa si ri i, o si kigbe pe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. On kò si ri i mọ: o si di aṣọ ara rẹ̀ mu, o si fà wọn ya si meji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíṣà rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì!” Èlíṣà kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.