2 Kings 2:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó fi aṣọ àwọ̀lékè tí ó já bọ́ sílẹ̀ lára Elija lu odò, ó sì kígbe pé, “Níbo ni OLUWA Ọlọrun Elija wà?” Lẹ́yìn náà odò pín sí meji, Eliṣa bá kọjá sí òdìkejì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si lù omi na, o si wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun Elijah wà? Nigbati on pẹlu si lù omi na, nwọn si pinyà sihin ati sọhun: Eliṣa si rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni OLÚWA Ọlọ́run Èlíjà wà?” Ó bèèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, ó sì rékọjá.