2 Kings 2:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
wọ́n ní, “Aadọta ọkunrin alágbára wà pẹlu àwa iranṣẹ rẹ, jọ́wọ́ jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ, bóyá Ẹ̀mí OLUWA tí ó gbé e lọ ti jù ú sílẹ̀ ní orí ọ̀kan ninu àwọn òkè agbègbè yìí, tabi ninu àfonífojì kan.” Eliṣa sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe rán wọn lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Wò o na, ãdọta ọkunrin alagbara mbẹ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ; awa bẹ̀ ọ, jẹ ki nwọn ki o lọ, ki nwọn ki o si wá oluwa rẹ lọ: bọya Ẹmi Oluwa ti gbé e sokè, o si ti sọ ọ sori ọkan ninu òke nla wọnni, tabi sinu afonifojì kan. On si wipe, Ẹ máṣe ranṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wò ó,” wọ́n wí pé, “Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára. Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá. Bóyá ẹ̀mí OLÚWA ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀.” “Rárá,” Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Má ṣe rán wọn.”