2 Kings 2:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yí ojú pada, tí ó rí wọn, ó ṣépè lé wọn ní orúkọ OLUWA, abo ẹranko beari meji sì jáde láti inú igbó, wọ́n fa mejilelogoji ninu àwọn ọmọ náà ya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si yipada, o si wò wọn, o si fi wọn bú li orukọ Oluwa. Abo-beari meji si jade lati inu igbó wá, nwọn si fà mejilelogoji ya ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ OLÚWA. Nígbà náà béárì méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì (42) lára àwọn ọ̀dọ́ náà.