2 Kings 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Bẹtẹli tọ Eliṣa wá, wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?” Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Beteli jade tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ wòlíì ní Bétélì jáde wá sí ọ̀dọ̀ Èlíṣà wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé OLÚWA yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?” “Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Èlíṣà dáhùn “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”