2 Kings 2:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Aadọta ninu àwọn ọmọ àwọn wolii náà sì dúró ní òkèèrè, wọ́n ń wò wọ́n. Elija ati Eliṣa sì dúró létí odò Jọdani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adọta ọkunrin ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro lati wò lòkere rére: awọn mejeji si duro li ẹba Jordani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jínjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Èlíjà àti Èlíṣà ti dúró ní Jọ́dánì.