2 Kings 2:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Elija bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó fi lu odò náà, odò sì pín sí meji títí tí Elija ati Eliṣa fi kọjá sí òdìkejì odò lórí ìyàngbẹ ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elijah si mu agbáda rẹ̀, o si lọ́ ọ lù, o si lù omi na, o si pin wọn ni iyà sihin ati sọhun, bẹ̃ni awọn mejeji si kọja ni ilẹ gbigbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíjà sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ̀.