2 Kings 20:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò kan Hesekaya ṣàìsàn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ kú. Wolii Aisaya ọmọ Amosi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o palẹ̀ ilé rẹ mọ́ nítorí pé kíkú ni o óo kú, o kò ní yè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LI ọjọ wọnni ni Hesekiah ṣe aisàn de oju-ikú. Isaiah woli ọmọ Amosi si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́; nitoriti iwọ o kú, iwọ kì yio si yè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Heṣekáyà ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Àìsáyà ọmọ Ámósì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò níí gbádùn.”