2 Kings 20:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hesekaya gba àwọn oníṣẹ́ náà ní àlejò. Ó fi gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀, fadaka, wúrà, turari, òróró iyebíye ati gbogbo ohun ìjà rẹ̀ hàn wọ́n. Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra rẹ̀ ati ní gbogbo ìjọba rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah si fi eti si ti wọn, o si fi gbogbo ile iṣura ohun iyebiye rẹ̀ hàn wọn, fadakà, ati wura, ati turari, ati ororo iyebiye, ati gbogbo ile ohun ihamọra rẹ̀, ati gbogbo eyiti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si nkan ni ile rẹ̀, tabi ni gbogbo ijọba rẹ̀, ti Hesekiah kò fi hàn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekáyà gba ìránṣẹ́ náà ó sì fi hàn wọ́n, gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé ìṣúra—sílífà, àti wúrà, àti tùràrí, àti òróró dáradára àti Ìhámọ́ra àti gbogbo èyí tí a rí lára ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan nínú ààfin rẹ̀ tàbí nínú gbogbo ìjọba rẹ̀ tí Heṣekáyà kò sì fi hàn wọ́n.