2 Kings 20:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni wolii Aisaya lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekaya, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin wọnyi ti wá, kí ni wọ́n sì sọ fún ọ?” Hesekaya dáhùn pé, “Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, láti Babiloni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Isaiah woli wá si ọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kili awọn ọkunrin wọnyi wi? ati nibo ni nwọn ti wá si ọdọ rẹ? Hesekiah si wipe, Ilu òkere ni nwọn ti wá, ani lati Babeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Àìṣáyà wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Heṣekáyà ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá?” “Lati ìlú jínjìn réré,” Hesekíáyà dáhùn. “Wọ́n wá láti Bábílónì.”