2 Kings 20:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
‘Àkókò kan ń bọ̀ tí wọn yóo kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ààfin rẹ lọ sí Babiloni, gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ látẹ̀yìnwá títí di òní ni wọn óo kó lọ, wọn kò ní fi nǹkankan sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, ti a o kó gbogbo nkan ti mbẹ ninu ile rẹ, ati eyiti awọn baba rẹ ti tò jọ titi di oni, lọ si Babeli: ohun kan kì yio kù, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ Òní, wọn yí ó gbe lọ sí Bábílónì, kò sí ohun tí yóò kù, ni OLÚWA wí.