2 Kings 20:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
n óo sì jẹ́ kí ó gbé ọdún mẹẹdogun sí i. N óo gba òun ati Jerusalẹmu lọ́wọ́ ọba Asiria. N óo sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí tèmi fúnra mi ati nítorí ìlérí tí mo ṣe fún Dafidi, iranṣẹ mi.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si bù ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ: emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria, emi o si dãbò bò ilu yi, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Ásíríà. Èmi yóò sì dábòbò ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi.’ ”