2 Kings 21:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ìparun wá sórí Jerusalẹmu ati Juda, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Kiyesi i, emi nmu iru ibi bayi wá sori Jerusalemu ati Juda, ti ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ, eti rẹ̀ mejeji yio ho.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jérúsálẹ́mù àti Júdà kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó.