2 Kings 21:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní òun óo jẹ Jerusalẹmu níyà bí òun ti jẹ Samaria níyà. Ó ní bí òun ti ṣe sí ìdílé Ahabu ati àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun óo gbá àwọn eniyan náà kúrò ní Jerusalẹmu, bí àwo tí a nù tí a sì da ojú rẹ̀ bolẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si nà okùn Samaria lori Jerusalemu, ati òjé-idiwọ̀n ile Ahabu: emi o si nù Jerusalemu bi enia ti nnù awokoto, o nnù u, o si ndori rẹ̀ kodò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀nkan tí a lò lórí Jérúsálẹ́mù àti lórí Ṣamáríà àti òjé ìdiwọ̀n ti a lòlò lórí ilé Áhábù. Èmi yóò sì nu Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù ti o n nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò.