2 Kings 21:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún àwọn ilé oriṣa tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti parun kọ́, ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún oriṣa Baali, ó sì gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, bí Ahabu, ọba Israẹli, ti gbẹ́ ẹ. Ó sì ń bọ àwọn ìràwọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀ ti parun; o si tẹ́ pẹpẹ fun Baali o si ṣe ere-oriṣa, bi Ahabu, ọba Israeli ti ṣe, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekíáyà tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ dìde fún Báálì ó sì ṣe ère-òrìṣà, gẹ́gẹ́ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.