2 Kings 21:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, a máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn aláfọ̀ṣẹ, a sì máa ṣe àlúpàyídà. Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó hùwà tí ó burú gidigidi níwájú OLUWA, ó sì rú ibinu OLUWA sókè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná, a si mã ṣe akiyesi afọṣẹ, a si mã ṣe alupàyida, a si mã bá awọn okú ati awọn oṣó lò: o hùwa buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó fi ọmọ ara rẹ̀ rúbọ̀ nínú iná, a máa ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ àti àlùpàyídà, ó sì máa ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó hùwà búburú púpọ̀ ní ojú OLÚWA láti mú un bínú.