2 Kings 21:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó gbẹ́ ère Aṣera tí ó gbé sinu ilé OLUWA, ibi tí OLUWA ti sọ fún Dafidi ati Solomoni pé, “Ninu ilé yìí, àní, ní Jerusalẹmu, ni mo yàn láàrin àwọn ìlú àwọn ẹ̀yà mejeejila Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ibi tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gbé ere oriṣa fifin kalẹ ti o ti ṣe ni ile na ti Oluwa sọ fun Dafidi ati Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, Ni ile yi, ati ni Jerusalemu, ti mo ti yàn ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì gbé fínfín ère òrìṣà tí ó ti ṣe ó sì gbé e sínú ilé OLÚWA, èyí tí OLÚWA ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Ṣólómónì, “Nínú ilé OLÚWA yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé.