2 Kings 21:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ati pé bí àwọn ọmọ Israẹli bá júbà àṣẹ mi, tí wọ́n pa òfin mi, tí Mose, iranṣẹ mi, fún wọn mọ́, n kò ní jẹ́ kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni emi kì yio si jẹ ki ẹsẹ̀ Israeli ki o yẹ̀ kuro mọ ni ilẹ ti mo fi fun awọn baba wọn; kiki bi nwọn o ba ṣe akiyesi lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo pa li aṣẹ fun wọn, ati gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi pa li aṣẹ fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn babańlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Móṣè fi fún wọn mọ́.”