2 Kings 22:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jedida ọmọ Adaya ará Bosikati.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ẸNI ọdun mẹjọ ni Josiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkanlelọgbọ̀n ni Jerusalemu, Orukọ iya rẹ̀ ni Jedida, ọmọbinrin Adaiah ti Boskati.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jòsáyà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jédídà ọmọbìnrin Ádáyà; ó wá láti Bósíkátì.