2 Kings 22:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ lọ bèèrè ohun tí a kọ sinu ìwé yìí lọ́wọ́ OLUWA fún èmi ati fún gbogbo eniyan Juda. OLUWA ń bínú sí wa gidigidi nítorí pé àwọn baba ńlá wa kò ṣe ohun tí ìwé yìí pa láṣẹ fún wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn enia, ati fun gbogbo Juda, niti ọ̀rọ iwe yi ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti o rú si wa, nitori awọn baba wa kò fi eti si ọ̀rọ iwe yi, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọwe silẹ fun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ OLÚWA fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Júdà nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Gíga ni ìbínú OLÚWA tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí; wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa.”