2 Kings 22:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hilikaya alufaa, ati Ahikamu ati Akibori ati Ṣafani ati Asaya bá lọ wádìí lọ́wọ́ wolii obinrin kan tí ń jẹ́ Hulida, tí ń gbé apá keji Jerusalẹmu. Ọkọ rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Tikifa, ọmọ Harihasi tíí máa ń ṣe ìtọ́jú yàrá tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún obinrin náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Hilkiah alufa, ati Ahikamu, ati Akbori, ati Ṣafani, ati Asahiah tọ̀ Hulda woli obinrin lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikfa, ọmọ Harhasi, alabojuto aṣọ (njẹ on ngbe Jerusalemu niha keji); nwọn si ba a sọ̀rọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hílíkíyà àlùfáà, Áhíkámù àti Ákíbórì pẹ̀lú Ṣáfánì, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà láti lọ bá a sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ aya Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háríhásì alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ní ìdà kejì.