2 Kings 22:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń sun turari sí àwọn oriṣa láti mú mi bínú nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Nítorí náà, inú mi yóo ru sí ibí yìí, kò sì ní rọlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti nsun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina ibinu mi yio rú si ibi yi, kì yio si rọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì tún ṣun tùràrí fún ọlọ́run mìíràn. Wọ́n sì mú mi bínú nípa gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn dá. Ìbínú mi yóò ru sí ibí yìí, kì yóò sì rọlẹ̀’