2 Kings 22:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn níti ọba Juda tí ó sọ pé kí ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ OLUWA, ẹ sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Nípa ọ̀rọ̀ tí ó ti gbọ́, nítorí pé ó ronupiwada,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn fun ọba Juda ti o rán nyin wá ibère lọdọ Oluwa, bayi li ẹnyin o sọ fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ fún ọba Júdà tí ó rán yín láti bèrè lọ́wọ́ OLÚWA, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí ìwọ ti gbọ́.