2 Kings 22:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLUWA, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì sun ẹkún nígbà tí ó gbọ́ ìlérí ìjìyà tí mo ṣe nípa Jerusalẹmu ati àwọn eniyan ibẹ̀, pé n óo sọ Jerusalẹmu di ahoro ati ibi tí àwọn eniyan yóo máa lo orúkọ rẹ̀ láti gégùn-ún. Ṣugbọn mo ti gbọ́ adura rẹ̀ nítorí pé ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, nigbati iwọ gbọ́ eyiti mo sọ si ibi yi, ati si awọn ara ilu na pe, nwọn o di ahoro ati ẹni-ègun, ti iwọ si fà aṣọ rẹ ya, ti o si sọkun niwaju mi; emi pẹlu ti gbọ́ tirẹ, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí ọkàn rẹ rọ̀, tí ìwọ sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú OLÚWA, nígbà tí ìwọ gbọ́ èyí tí mo sọ sí ibí yìí àti sí àwọn ènìyàn rẹ pé wọn yóò di ahoro àti ẹni ègún tí ìwọ sì fa aṣọ ọ̀ rẹ ya pẹ̀lú níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ, ni OLÚWA wí.