2 Kings 23:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí àwọn ọba Juda kọ́ sórí ilé Ahasi ninu ààfin lulẹ̀, pẹlu àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí Manase kọ́ sinu àwọn àgbàlá meji tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó fọ́ gbogbo wọn túútúú, ó sì kó wọn dà sí àfonífojì Kidironi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹpẹ wọnni ti mbẹ lori iyara òke Ahasi, ti awọn ọba Juda ti tẹ́, ati pẹpẹ wọnni ti Manasse ti tẹ́ li ãfin mejeji ile Oluwa ni ọba wó lulẹ, o si yara lati ibẹ, o si da ekuru wọn sinu odò Kidroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Júdà ti wọ́n gbé dúró ní ori òrùlé lẹ́bá yàrá òkè ti Áhásì pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Mánásè ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé OLÚWA. Ó sí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Ó sì da ekuru wọn sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì.