2 Kings 23:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Josaya wó gbogbo ibi gíga tí wọn tún ń pè ní òkè ìdíbàjẹ́, tí Solomoni kọ́ sí apá ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu, ní ìhà gúsù Òkè Olifi, fún àwọn oriṣa Aṣitoreti, ohun ìríra àwọn ará Sidoni, ati Kemoṣi, ohun ìríra àwọn ará Moabu, ati fún Milikomu, ohun ìríra àwọn ará Amoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ibi giga wọnni ti o wà niwaju Jerusalemu, ti o wà li ọwọ ọtún òke idibàjẹ, ti Solomoni ọba Israeli ti kọ́ fun Aṣtoreti ohun irira awọn ara Sidoni, ati fun Kemoṣi ohun irira awọn ara Moabu, ati fun Milkomu ohun-irira awọn ọmọ Ammoni li ọba sọ di ẽri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Jérúsálẹ́mù ní ìhà gúṣù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ fún Ásítórétì ọlọ́run ìríra àwọn ará Ṣídónì, fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra àwọn ará Móábù àti fún Mólékì, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ámónì.