2 Kings 23:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu, pẹpẹ ti o ti wà ni Beteli, ati ibi giga ti Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ti tẹ́, ati pẹpẹ na, ati ibi giga na ni o wó lulẹ, o si sun ibi giga na, o si lọ̀ ọ lũlu, o si sun ere-oriṣa na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àní pẹpẹ tí ó wà ní Bétélì ibi gíga tí Jéróbóámù ọmọ Nébátí dá. Tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti ṣẹ̀—Àní pẹpẹ náà àti ibi gíga tí ó fọ́ túútúú. Ó jó àwọn ibi gíga, ó sì lọ̀ ọ́ sí ẹ̀tù, ó sì ṣun òpó Áṣérà pẹ̀lú.