2 Kings 23:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó bèèrè pé, “Ọ̀wọ̀n ibojì ta ni mò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí?” Àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli sì dáhùn pé, “Ibojì wolii tí ó wá láti Juda tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ò ń ṣe sí pẹpẹ ìrúbọ yìí ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li o wipe, Ọwọ̀n isa-okú wo li eyi ti mo ri nì? Awọn enia ilu na si sọ fun u pe, Isà-okú enia Ọlọrun nì ni, ti o ti Juda wá, ti o si kede nkan wọnyi ti iwọ ti ṣe si pẹpẹ Beteli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì béèrè, pé “Kí ni ọwọ́n iṣà òkú yẹn tí mo rí?” Àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wí pé, “Ó sàmì sí iṣà òkú ènìyàn Ọlọ́run tí ó wá láti Júdà, tí ó sì kéde ìdojúkọ pẹpẹ Bétélì, ohun kan wọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe sí wọn.”