2 Kings 23:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní gbogbo àwọn ìlú Israẹli ni Josaya ti wó àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọba Israẹli kọ́ tí ó bí OLUWA ninu. Bí ó ti ṣe pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Bẹtẹli ni ó ṣe àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu gbogbo ile ibi-giga wọnni ti o wà ni ilu Samaria wọnni, ti awọn ọba Israeli ti kọ́ lati rú ibinu Oluwa soke ni Josiah mu kuro, o si ṣe si wọn gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti o ṣe ni Beteli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Bétélì, Jòṣíàh sì kúrò, ó sì ba gbogbo ojúbọ òrìṣà ti ibi gíga jẹ́, tí àwọn ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ sí àwọn ìlú ní Ṣamáríà, tí ó ti mú OLÚWA bínú.