2 Kings 23:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo wọn lọ sí ilé OLUWA pẹlu àwọn alufaa ati àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan, àtọmọdé àtàgbà wọn. Ọba bá ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo awọn enia Juda ati gbogbo olugbe Jerusalemu pẹlu rẹ̀, ati awọn alufa, ati awọn woli ati gbogbo enia, ati ewe ati àgba: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó gòkè lọ sí ilé OLÚWA pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèkéé sí ńlá. Ó kàá sí etí igbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé OLÚWA.