2 Kings 23:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Josaya ọba lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó jáde kúrò ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ère, àwọn oriṣa, ati gbogbo ohun ìbọ̀rìṣà kúrò ní Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu òfin tí ó wà ninu ìwé tí Hilikaya olórí alufaa rí ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu awọn ti mba awọn okú lò, ati awọn oṣo, ati awọn ere, ati awọn oriṣa, ati gbogbo irira ti a ri ni ilẹ Juda ati ni Jerusalemu ni Josiah kó kuro, ki o le mu ọ̀rọ ofin na ṣẹ ti a ti kọ sinu iwe ti Hilkiah alufa ri ni ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síwájú sí, Jòsíáyà sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Júdà àti ní Jérúsálẹ́mù. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hílíkíyà àlùfáà ti rí nínú ilé OLÚWA.