2 Kings 23:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ pé, “N óo ṣe ohun tí mo ṣe sí Israẹli sí Juda, n óo pa àwọn eniyan Juda run, n óo sì kọ Jerusalẹmu, ìlú tí mo yàn sílẹ̀, ati ilé OLUWA tí mo yàn fún ìsìn mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wipe, Emi o si mu Juda kuro loju mi pẹlu, bi mo ti mu Israeli kuro, emi o si ta ilu Jerusalemu yi nù, ti mo ti yàn, ati ile eyiti mo wipe, Orukọ mi yio wà nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí pé, “Èmi yóò mú Júdà kúrò pẹ̀lú níwájú mi, bí mo ti mú Ísírẹ́lì, èmi yóò sì kó Jérúsálẹ́mù, ìlú ńlá tí mo yàn àti ilé OLÚWA yìí, nípa èyí tí mo sọ, ‘Níbẹ̀ ni orúkọ mi yóò wà?’ ”