2 Kings 23:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba dúró sí ààyè rẹ̀, lẹ́bàá òpó, ó bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa rìn ní ọ̀nà OLUWA ati láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ati láti mú gbogbo ohun tí ó wà ninu Ìwé náà ṣẹ. Gbogbo àwọn eniyan sì ṣe ìlérí láti pa majẹmu náà mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si duro ni ibuduro na, o si dá majẹmu niwaju Oluwa, lati mã fi gbogbo aìya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati mu ọ̀rọ majẹmu yi ṣẹ, ti a ti kọ ninu iwe yi. Gbogbo awọn enia si duro si majẹmu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì dúró lẹ́bà òpó, ó sì sọ májẹ̀mú di titun níwájú OLÚWA láti tẹ̀lé OLÚWA àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, ìlànà àti òfin pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí rẹ̀, àti láti ṣe ìwádìí àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn sì ṣèlérí fúnra wọn sí májẹ̀mú náà.