2 Kings 23:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Megido wọn gbé e wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì rẹ̀. Àwọn eniyan Juda sì fi òróró yan Jehoahasi ọmọ rẹ̀ ní ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e li okú ninu kẹkẹ́ lati Megiddo lọ, nwọn si mu u wá si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni isà-okú on tikalarẹ̀. Awọn enia ilẹ na si mu Jehoahasi ọmọ Josiah, nwọn si fi ororo yàn a, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìránṣẹ́ Jòṣíáyà gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Mègídò sí Jérúsálẹ́mù ó sì sin ín sínú iṣà òkú rẹ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jéhóáhásì ọmọ Jòṣíáyà. Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò bàbá a rẹ̀.