2 Kings 23:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni ọdún mẹtalelogun ni Jehoahasi nígbà tí ó jọba ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya, ará Libina.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóáhásì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Hámútalì ọmọbìnrin Jeremíáyà; ó wá láti Líbínánì.