2 Kings 23:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Josaya bá pàṣẹ fún Hilikaya olórí alufaa, ati àwọn alufaa yòókù ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, pé kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò ìsìn oriṣa Baali, ati ti oriṣa Aṣera, ati ti àwọn ìràwọ̀ jáde. Ọba jó àwọn ohun èlò náà níná lẹ́yìn odi ìlú, lẹ́bàá àfonífojì Kidironi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó eérú wọn lọ sí Bẹtẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si paṣẹ fun Hilkiah olori alufa, ati awọn alufa ẹgbẹ keji, ati awọn alabojuto iloro, lati kó gbogbo ohun-èlo ti a ṣe fun Baali, ati fun ere òriṣa, ati fun gbogbo ogun ọrun jade kuro ni tempili Oluwa: o si sun wọn lẹhin ode Jerusalemu ninu pápa Kidroni, o si kó ẽru wọn lọ si Beteli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì pàṣẹ fún Hílíkíáyà olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lée ní ipò àti àwọn olùsọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé OLÚWA gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Báálì àti Áṣérà àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jérúsálẹ́mù ní pápá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Bétélì.