2 Kings 23:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn alufaa tí àwọn ọba Juda ti yàn láti máa rúbọ lórí pẹpẹ oriṣa ní àwọn ìlú Juda ati ní agbègbè Jerusalẹmu ni Josaya dá dúró, ati gbogbo àwọn tí wọn ń rúbọ sí oriṣa Baali, sí oòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, ati àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní òfuurufú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si dá awọn baba-loriṣa lẹkun, ti awọn ọba Juda ti yàn lati ma sun turari ni ibi giga ni ilu Juda wọnni, ati ni ibi ti o yi Jerusalemu ka; awọn pẹlu ti nsun turari fun Baali, fun õrùn, ati fun òṣupa, ati fun awọn àmi mejila ìrawọ, ati fun gbogbo ogun ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Júdà láti ṣun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Júdà àti àwọn tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Báálì, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.