2 Kings 23:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kó gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí àfonífojì Kidironi lẹ́yìn Jerusalẹmu. Ó sun wọ́n níná níbẹ̀, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì fọ́n eérú wọn ká sórí ibojì àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gbé ere-oriṣa jade kuro ni ile Oluwa, sẹhin ode Jerusalemu lọ si odò Kidroni, o si sun u nibi odò Kidroni, o si lọ̀ ọ lũlu, o si dà ẽrú rẹ̀ sori isà-okú awọn ọmọ enia na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú ère òrìṣà láti ilé OLÚWA sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì ní ìta Jérúsálẹ́mù, ó sì ṣun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí atíkè ó sì fọ́n ekuru náà sórí iṣà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀.